Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 4:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ṣugbọn tani ha kẹgàn ọjọ ohun kekere? nitori nwọn o yọ̀, nwọn o si ri iwọ̀n lọwọ Serubbabeli pẹlu meje wọnni; awọn ni oju Oluwa, ti o nsare sihin sọhun ni gbogbo aiye.

11. Mo si dahun, mo si sọ fun u pe, Kini awọn igi olifi meji wọnyi jasi, ti o wà li apá ọtun fitilà ati li apá osì rẹ̀?

12. Mo si tún dahùn, mo si sọ fun u pe, Kini awọn ẹka meji igi olifi wọnyi jasi, ti ntú ororo wurà jade lori wọn lati inu ikòko wurà.

13. O si dahùn, o wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, N kò mọ̀, oluwa mi.

14. O si wipe, Awọn meji wọnyi ni awọn ti a fi ororo yàn, ti o duro tì Oluwa gbogbo aiye.

Ka pipe ipin Sek 4