Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 3:4-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. O si dahùn o wi fun awọn ti o duro niwaju rẹ̀ pe, Bọ aṣọ ẽri nì kuro li ara rẹ̀. O si wi fun u pe, Wò o, mo mu ki aiṣedẽde rẹ kuro lọdọ rẹ, emi o si wọ̀ ọ li aṣọ ẹyẹ.

5. Mo si wipe, Jẹ ki wọn fi lawàni mimọ́ wé e li ori. Nwọn si fi lawàni mimọ́ wé e lori, nwọn si fi aṣọ wọ̀ ọ. Angeli Oluwa si duro tì i.

6. Angeli Oluwa si tẹnu mọ fun Joṣua pe,

7. Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bi iwọ o ba rìn li ọ̀na mi, bi iwọ o ba si pa aṣẹ mi mọ, iwọ o si ṣe idajọ ile mi pẹlu, iwọ o si pa ãfin mi mọ pẹlu, emi o si fun ọ li àye ati rìn lãrin awọn ti o duro yi.

8. Gbọ́ na, iwọ Joṣua olori alufa, iwọ, ati awọn ẹgbẹ́ rẹ ti o joko niwaju rẹ: nitori ẹni iyanu ni nwọn: nitori kiyesi i, emi o mu iranṣẹ mi, ẸKA, wá.

9. Nitori kiyesi i, okuta ti mo ti gbe kalẹ niwaju Joṣua; lori okuta kan ni oju meje o wà: kiyesi i, emi o fin finfin rẹ̀, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi o si mu aiṣedẽde ilẹ na kuro ni ijọ kan.

10. Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, ni ọjọ na ni olukuluku yio pe ẹnikeji rẹ̀ sabẹ igi àjara ati sabẹ igi ọpọ̀tọ.

Ka pipe ipin Sek 3