orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 2 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìran nípa Okùn Ìwọ̀n

1. MO si tun gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti on ti okùn-iwọ̀n lọwọ rẹ̀.

2. Mo si wipe, Nibo ni iwọ nlọ? o si wi fun mi pe, Lati wọ̀n Jerusalemu, lati ri iye ibú rẹ̀, ati iye gigùn rẹ̀.

3. Si kiyesi i, angeli ti o mba mi sọ̀rọ jade lọ, angeli miran si jade lọ ipade rẹ̀.

4. O si wi fun u pe, Sare, sọ fun ọdọmọkunrin yi wipe, a o gbe inu Jerusalemu bi ilu ti kò ni odi nitori ọ̀pọ enia ati ohun-ọsìn inu rẹ̀:

5. Oluwa wipe, Emi o si jẹ odi iná fun u yika, emi o si jẹ ogo lãrin rẹ̀.

Pípe Àwọn tí A kó lẹ́rú pada Wálé

6. Ã! ã! sá kuro ni ilẹ ariwa, ni Oluwa wi; nitoripe bi afẹfẹ mẹrin ọrun ni mo tu nyin kakiri, ni Oluwa wi.

7. Sioni, gba ara rẹ là, iwọ ti o mba ọmọbinrin Babiloni gbe.

8. Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; lẹhìn ogo li o ti rán mi si awọn orilẹ-ède ti nkó nyin: nitori ẹniti o tọ́ nyin, o tọ́ ọmọ oju rẹ̀.

9. Nitori kiyesi i, emi o gbọ̀n ọwọ mi si ori wọn, nwọn o si jẹ ikogun fun iranṣẹ wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi.

10. Kọrin ki o si yọ̀, iwọ ọmọbinrin Sioni: sa wò o, mo de, emi o si gbe ãrin rẹ, ni Oluwa wi.

11. Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède ni yio dapọ̀ mọ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si di enia mi; emi o si gbe ãrin rẹ, iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si ọ.

12. Oluwa o si jogún Juda iní rẹ̀, nilẹ̀ mimọ́, yio si tun yàn Jerusalemu.

13. Ẹ dakẹ, gbogbo ẹran-ara niwaju Oluwa: nitori a ji i lati ibùgbe mimọ́ rẹ̀ wá.