Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 14:5-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ẹnyin o si sá si afonifojì oke mi wọnni: nitoripe afonifoji oke na yio de Asali: nitõtọ, ẹnyin o sa bi ẹ ti sa fun ìṣẹ̀lẹ̀ nì li ọjọ Ussiah ọba Juda: Oluwa Ọlọrun mi yio si wá, ati gbogbo awọn Ẹni-mimọ́ pẹlu rẹ̀.

6. Yio si ṣe li ọjọ na, imọlẹ kì yio mọ́, bẹ̃ni kì yio ṣõkùnkun.

7. Ṣugbọn yio jẹ ọjọ kan mimọ̀ fun Oluwa, kì iṣe ọsan, kì iṣe oru; ṣugbọn yio ṣe pe, li aṣãlẹ imọlẹ yio wà.

8. Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃.

9. Oluwa yio si jọba lori gbogbo aiye: li ọjọ na ni Oluwa kan yio wà, orukọ rẹ̀ yio si jẹ ọkan.

10. A o yi gbogbo ilẹ padà bi pẹtẹlẹ kan lati Geba de Rimmoni lapa gusu Jerusalemu: a o si gbe e soke, yio si gbe ipò rẹ̀, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekini, de ibode igun nì, ati lati ile iṣọ Hananeeli de ibi ifunti waini ọba.

11. Enia yio si ma gbe ibẹ̀, kì yio si si iparun yanyan mọ; Ṣugbọn a o ma gbe Jerusalemu lailewu.

12. Eyi ni yio si jẹ àrun ti Oluwa yio fi kọlu gbogbo awọn enia ti o ti ba Jerusalemu ja; ẹran-ara wọn yio rù nigbati wọn duro li ẹsẹ̀ wọn, oju wọn yio si rà ni ihò wọn, ahọn wọn yio si jẹrà li ẹnu wọn.

13. Yio si ṣe li ọjọ na, irọkẹ̀kẹ nla lati ọdọ Oluwa wá yio wà lãrin wọn; nwọn o si dì ọwọ ara wọn mu, ọwọ rẹ̀ yio si dide si ọwọ ẹnikeji rẹ̀.

14. Juda pẹlu yio si jà ni Jerusalemu; ọrọ̀ gbogbo awọn keferi ti o wà kakiri li a o si kojọ, wurà, ati fàdakà, ati aṣọ, li ọpọlọpọ.

Ka pipe ipin Sek 14