Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 14:10-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. A o yi gbogbo ilẹ padà bi pẹtẹlẹ kan lati Geba de Rimmoni lapa gusu Jerusalemu: a o si gbe e soke, yio si gbe ipò rẹ̀, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekini, de ibode igun nì, ati lati ile iṣọ Hananeeli de ibi ifunti waini ọba.

11. Enia yio si ma gbe ibẹ̀, kì yio si si iparun yanyan mọ; Ṣugbọn a o ma gbe Jerusalemu lailewu.

12. Eyi ni yio si jẹ àrun ti Oluwa yio fi kọlu gbogbo awọn enia ti o ti ba Jerusalemu ja; ẹran-ara wọn yio rù nigbati wọn duro li ẹsẹ̀ wọn, oju wọn yio si rà ni ihò wọn, ahọn wọn yio si jẹrà li ẹnu wọn.

13. Yio si ṣe li ọjọ na, irọkẹ̀kẹ nla lati ọdọ Oluwa wá yio wà lãrin wọn; nwọn o si dì ọwọ ara wọn mu, ọwọ rẹ̀ yio si dide si ọwọ ẹnikeji rẹ̀.

14. Juda pẹlu yio si jà ni Jerusalemu; ọrọ̀ gbogbo awọn keferi ti o wà kakiri li a o si kojọ, wurà, ati fàdakà, ati aṣọ, li ọpọlọpọ.

15. Bẹ̃ni àrun ẹṣin, ibãka, ràkumi, ati ti kẹtẹkẹtẹ, yio si wà, ati gbogbo ẹranko ti mbẹ ninu agọ wọnyi gẹgẹ bi àrun yi.

16. Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o kù ninu gbogbo awọn orilẹ-ède ti o dide si Jerusalemu yio ma goke lọ lọdọdun lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati lati pa àse agọ wọnni mọ.

17. Yio si ṣe, ẹnikẹni ti kì yio goke wá ninu gbogbo idile aiye si Jerusalemu lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, fun wọn ni òjo kì yio rọ̀.

18. Bi idile Egipti kò ba si goke lọ, ti nwọn kò si wá, ti kò ni òjo; àrun na yio wà, ti Oluwa yio fi kọlù awọn keferi ti kò goke wá lati pa àse agọ na mọ.

19. Eyi ni yio si jẹ iyà Egipti, ati iyà gbogbo orilẹ-ède ti kò goke wá lati pa àse agọ mọ.

20. Li ọjọ na ni MIMỌ SI OLUWA yio wà lara ṣaworo ẹṣin; ati awọn ikòko ni ile Oluwa yio si dàbi awọn ọpọ́n wọnni niwaju pẹpẹ.

21. Nitõtọ, gbogbo ikòko ni Jerusalemu ati ni Juda yio jẹ mimọ́ si Oluwa awọn ọmọ-ogun: ati gbogbo awọn ti nrubọ yio wá, nwọn o si gbà ninu wọn, nwọn o si bọ̀ ninu rẹ̀: li ọjọ na ni ara Kenaani kì yio si si mọ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun.

Ka pipe ipin Sek 14