Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 14:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KIYESI i, ọjọ Oluwa mbọ̀, a o si pin ikogun rẹ lãrin rẹ.

2. Nitori emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si Jerusalemu fun ogun; a o si kó ilu na, a o si kó awọn ile, a o si bà awọn obinrin jẹ, abọ̀ ilu na yio lọ si igbèkun, a kì yio si ké iyokù awọn enia na kuro ni ilu na.

3. Nigbana ni Oluwa yio jade lọ, yio si ba awọn orilẹ-ède wọnni jà, gẹgẹ bi iti ijà li ọjọ ogun.

4. Ẹsẹ̀ rẹ̀ yio si duro li ọjọ na lori oke Olifi, ti o wà niwaju Jerusalemu ni ila-õrun, oke Olifi yio si là meji si ihà ila-õrun ati si ihà iwọ̀-õrun, afonifojì nlanla yio wà: idajì oke na yio si ṣi sihà ariwa, ati idajì rẹ̀ siha gusu.

5. Ẹnyin o si sá si afonifojì oke mi wọnni: nitoripe afonifoji oke na yio de Asali: nitõtọ, ẹnyin o sa bi ẹ ti sa fun ìṣẹ̀lẹ̀ nì li ọjọ Ussiah ọba Juda: Oluwa Ọlọrun mi yio si wá, ati gbogbo awọn Ẹni-mimọ́ pẹlu rẹ̀.

Ka pipe ipin Sek 14