Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 11:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Emi o si bọ́ ẹran abọ́pa, ani ẹnyin otoṣi ninu ọwọ́ ẹran. Mo si mu ọpa meji sọdọ; mo pe ọkan ni Ẹwà, mo si pe ekeji ni Amure; mo si bọ́ ọwọ́-ẹran na.

8. Oluṣọ agutan mẹta ni mo si ke kuro li oṣu kan; ọkàn mi si korira wọn, ọkàn wọn pẹlu si korira mi.

9. Mo si wipe, emi kì yio bọ nyin: eyi ti nkú lọ, jẹ ki o kú; eyi ti a o ba si ke kuro, jẹ ki a ke e kuro; ki olukuluku ninu awọn iyokù jẹ ẹran-ara ẹnikeji rẹ̀.

10. Mo si mu ọpa mi, ani Ẹwà, mo si ṣẹ ẹ si meji, ki emi ba le dà majẹmu mi ti mo ti ba gbogbo awọn enia ni da.

11. O si dá li ọjọ na; bẹ̃ni awọn otoṣi ninu ọwọ́-ẹran nì ti o duro tì mi mọ̀ pe, ọ̀rọ Oluwa ni.

12. Mo si wi fun wọn pe, Bi o ba dara li oju nyin, ẹ fun mi ni owo-ọ̀ya mi: bi bẹ̃kọ, ẹ jọwọ rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn wọ̀n ọgbọ̀n owo fadakà fun iye mi.

13. Oluwa si wi fun mi pe, Sọ ọ si amọkòko: iye daradara na ti nwọn yọwó mi si. Mo si mu ọgbọ̀n owo fadakà na, mo si sọ wọn si amọkòko ni ile Oluwa.

14. Mo si ṣẹ ọpa mi keji, ani Amure, si meji, ki emi ki o le yà ibatan ti o wà lãrin Juda ati lãrin Israeli.

Ka pipe ipin Sek 11