Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 11:4-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Bayi li Oluwa Ọlọrun mi wi; Bọ́ ọwọ́-ẹran abọ́pa.

5. Ti awọn oluwa wọn npa wọn, ti nwọn kò si kà ara wọn si pe nwọn jẹbi: ati awọn ti ntà wọn wipe, Ibukún ni fun Oluwa, nitoriti mo di ọlọrọ̀: awọn oluṣọ agutan wọn kò si ṣãnu wọn.

6. Nitori emi kì yio ṣãnu fun awọn ara ilẹ na mọ, li Oluwa wi; si kiye si i, emi o fi olukuluku enia le aladugbo rẹ̀ lọwọ, ati le ọwọ ọba rẹ̀: nwọn o si fọ́ ilẹ na, emi kì yio si gbà wọn lọwọ wọn.

7. Emi o si bọ́ ẹran abọ́pa, ani ẹnyin otoṣi ninu ọwọ́ ẹran. Mo si mu ọpa meji sọdọ; mo pe ọkan ni Ẹwà, mo si pe ekeji ni Amure; mo si bọ́ ọwọ́-ẹran na.

Ka pipe ipin Sek 11