Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 1:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI oṣù kẹjọ, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli, pe,

2. Oluwa ti binu pupọ̀ si awọn baba nyin.

3. Nitorina iwọ wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ yipadà si mi, emi o si yipadà si nyin, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

4. Ẹ má dàbi awọn baba nyin, awọn ti awọn woli iṣãju ti ké si wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Ẹ yipadà nisisiyi kuro li ọ̀na buburu nyin, ati kuro ninu ìwa-buburu nyin: ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò fetisi ti emi, ni Oluwa wi.

5. Awọn baba nyin, nibo ni nwọn wà? ati awọn woli, nwọn ha wà titi aiye?

6. Ṣugbọn ọ̀rọ mi ati ilàna mi, ti mo pa li aṣẹ fun awọn iranṣẹ mi woli, nwọn kò ha fi mu awọn baba nyin? nwọn si padà nwọn wipe, Gẹgẹ bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rò lati ṣe si wa, gẹgẹ bi ọ̀na wa, ati gẹgẹ bi iṣe wa, bẹ̃ni o ti ṣe si wa.

7. Li ọjọ kẹrinlelogun oṣù kọkanla, ti iṣe oṣù Sebati, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli wá, pe,

8. Mo ri li oru, si wò o, ọkunrin kan ngun ẹṣin pupa kan, on si duro lãrin awọn igi mirtili ti o wà ni ibi õji; lẹhìn rẹ̀ si li ẹṣin pupa, adíkalà, ati funfun gbe wà.

9. Nigbana ni mo wipe, Kini wọnyi oluwa mi? Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, emi o fi ohun ti wọnyi jẹ hàn ọ.

10. Ọkunrin ti o duro lãrin awọn igi mirtili si dahùn o si wipe, Wọnyi li awọn ti Oluwa ti rán lati ma rìn sokè sodò li aiye.

Ka pipe ipin Sek 1