Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rut 4:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Boasi lọ si ẹnu-bode, o si joko nibẹ̀: si kiyesi i, ibatan na ẹniti Boasi sọ̀rọ rẹ̀ nkọja; o si pe, Iwọ alamọrin! yà, ki o si joko nihin. O si yà, o si joko.

2. O si mú ọkunrin mẹwa ninu awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ joko nihin. Nwọn si joko.

3. O si wi fun ibatan na pe, Naomi, ẹniti o ti ilẹ Moabu pada wa, o ntà ilẹ kan, ti iṣe ti Elimeleki arakunrin wa:

4. Mo si rò lati ṣí ọ leti rẹ̀, wipe, Rà a niwaju awọn ti o joko nihin, ati niwaju awọn àlagba awọn enia mi. Bi iwọ o ba rà a silẹ, rà a silẹ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rà a silẹ, njẹ wi fun mi, ki emi ki o le mọ̀: nitoriti kò sí ẹnikan lati rà a silẹ lẹhin rẹ; emi li o si tẹle ọ. On si wipe, Emi o rà a silẹ.

5. Nigbana ni Boasi wipe, Li ọjọ́ ti iwọ ba rà ilẹ na li ọwọ́ Naomi, iwọ kò le ṣe àirà a li ọwọ́ Rutu ara Moabu pẹlu, aya ẹniti o kú, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀.

6. Ibatan na si wipe, Emi kò le rà a silẹ fun ara mi, ki emi má ba bà ilẹ-iní mi jẹ́: iwọ rà eyiti emi iba rà silẹ; nitori emi kò le rà a.

Ka pipe ipin Rut 4