Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 8:15-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ.

16. Nipasẹ mi li awọn ijoye nṣolori, ati awọn ọ̀lọtọ̀, ani gbogbo awọn onidajọ aiye.

17. Mo fẹ awọn ti o fẹ mi; awọn ti o si wá mi ni kutukutu yio ri mi.

18. Ọrọ̀ ati ọlá mbẹ lọwọ mi, ani ọrọ̀ daradara ati ododo.

19. Ere mi ta wura yọ; nitõtọ, jù wura daradara lọ: ati ọrọ̀ mi jù fadaka àṣayan lọ.

20. Emi nrìn li ọ̀na ododo, larin ipa-ọ̀na idajọ:

21. Ki emi ki o le mu awọn ti o fẹ mi jogun ohun-ini mi, emi o si fi kún iṣura wọn.

22. Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ.

23. A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà.

24. Nigbati ọgbun kò si, a ti bi mi; nigbati kò si orisun ti o kún fun omi pipọ.

25. Ki a to fi idi awọn òke-nla sọlẹ, ṣãju awọn òke li a ti bi mi:

26. Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye.

Ka pipe ipin Owe 8