1. ỌGBỌ́N kò ha nkigbe bi? Oye kò ha gbé ohùn rẹ̀ soke bi?
2. O duro li ori ibi-giga wọnni, lẹba ọ̀na, nibi ipa-ọ̀na wọnni.
3. O nke li ẹnu-ọ̀na, ati ni ibode ilu, li atiwọ̀ oju ilẹkun.
4. Ẹnyin enia li emi npè; ohùn mi si nkọ si awọn ọmọ enia.
5. Ẹnyin òpe, ẹ mọ̀ ọgbọ́n: ati ẹnyin aṣiwere ki ẹnyin ki o ṣe alaiya oye.
6. Ẹ gbọ́, nitori ti emi o sọ̀rọ ohun ti o dara, ati ṣiṣi ète mi yio sọ̀rọ ohun titọ.
7. Nitori ti ẹnu mi yio sọ̀rọ otitọ; ìwa-buburu si ni irira fun ète mi.
8. Ninu ododo ni gbogbo ọ̀rọ ẹnu mi; kò si ẹ̀tan kan tabi arekereke ninu wọn.
9. Gbangba ni gbogbo wọn jasi fun ẹniti o yé, o si tọ́ fun awọn ti o nwá ìmọ ri.