Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 7:12-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nisisiyi o jade, nisisiyi o wà ni igboro, o si mba ni ibi igun ile gbogbo.)

13. Bẹ̃li o dì i mu, o si fẹnu kò o li ẹnu, o si fi ọ̀yájú wi fun u pe,

14. Ọrẹ́, alafia mbẹ lọwọ mi, loni ni mo ti san ẹjẹ́ mi.

15. Nitorina ni mo ṣe jade wá pade rẹ, lati ṣe afẹri oju rẹ, emi si ri ọ.

16. Emi ti fi aṣọ titẹ ọlọnà tẹ́ akete mi, ọlọnà finfin ati aṣọ ọ̀gbọ daradara ti Egipti.

17. Emi ti fi turari olõrùn didùn ti mirra, aloe, ati kinnamoni si akete mi.

18. Wá, jẹ ki a gbà ẹkún ifẹ wa titi yio fi di owurọ, jẹ ki a fi ifẹ tù ara wa lara.

19. Nitoripe bãle kò si ni ile, o re àjo ọ̀na jijin:

20. O mu àsuwọn owo kan lọwọ rẹ̀, yio si de li oṣupa arànmọju.

21. Ọ̀rọ rẹ̀ daradara li o fi mu u fẹ, ipọnni ète rẹ̀ li o fi ṣẹ́ ẹ li apa.

22. On si tọ̀ ọ lọ lẹsẹkanna bi malu ti nlọ si ibupa, tabi bi aṣiwere ti nlọ si ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́.

23. Titi ọfà fi gún u li ẹ̀dọ̀; bi ẹiyẹ ti nyara bọ sinu okùn, ti kò si mọ̀ pe fun ẹmi on ni.

24. Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ẹ feti si temi, ki ẹ si fiye si ọ̀rọ ẹnu mi.

25. Máṣe jẹ ki aiya rẹ̀ ki o tẹ̀ si ọ̀na rẹ̀, máṣe ṣina lọ si ipa-ọ̀na rẹ̀.

26. Nitori ọ̀pọlọpọ enia li o ṣá lulẹ; nitõtọ ọ̀pọlọpọ alagbara enia li a ti ọwọ rẹ̀ pa.

27. Ile rẹ̀ li ọ̀na ọrun-apadi, ti nsọkalẹ lọ si iyẹwu ikú.

Ka pipe ipin Owe 7