Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 5:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ.

16. Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita.

17. Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ.

18. Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ.

19. Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba.

20. Ọmọ mi, ẽṣe ti iwọ o fi ma yọ̀ ninu ifẹ ajeji obinrin, ti iwọ o fi gbá aiya ajeji obinrin mọra?

21. Nitoripe ọ̀na enia mbẹ niwaju Oluwa, o si nṣiwọ̀n irin wọn gbogbo.

22. Ẹ̀ṣẹ ẹni-buburu ni yio mu ontikararẹ̀, okùn ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀ yio si dì i mu.

23. Yio kú li aigbà ẹkọ́, ati ninu ọ̀pọlọpọ were rẹ̀ yio si ma ṣina kiri.

Ka pipe ipin Owe 5