Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 5:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi.

14. Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ.

15. Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ.

16. Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita.

17. Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ.

18. Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ.

19. Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba.

20. Ọmọ mi, ẽṣe ti iwọ o fi ma yọ̀ ninu ifẹ ajeji obinrin, ti iwọ o fi gbá aiya ajeji obinrin mọra?

21. Nitoripe ọ̀na enia mbẹ niwaju Oluwa, o si nṣiwọ̀n irin wọn gbogbo.

22. Ẹ̀ṣẹ ẹni-buburu ni yio mu ontikararẹ̀, okùn ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀ yio si dì i mu.

23. Yio kú li aigbà ẹkọ́, ati ninu ọ̀pọlọpọ were rẹ̀ yio si ma ṣina kiri.

Ka pipe ipin Owe 5