1. ỌMỌ mi, fiyesi ọgbọ́n mi, ki o si dẹti rẹ si oye mi.
2. Lati ma pa ironu mọ́, ati ki ète rẹ ki o le ma pa ìmọ mọ́.
3. Nitori ti ète awọn ajeji obinrin a ma kán bi oyin, ẹnu rẹ̀ si kunna ju ororo lọ:
4. Ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ koro bi idápa, o si mú bi idà olojumeji.
5. Ẹsẹ rẹ̀ nsọkalẹ lọ sinu ikú, ìrin-ẹsẹ rẹ̀ de ipo-okú.
6. Ki iwọ má ba ja ipa-ọ̀na ìye, ipa-ọ̀na rẹ̀ a ma yi sihin yi sọhun, on kò si mọ̀.
7. Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi.
8. Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀:
9. Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka;