Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 31:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Jẹ ki o mu, ki o si gbagbe aini rẹ̀, ki o má si ranti òṣi rẹ̀ mọ́.

8. Yà ẹnu rẹ fun ayadi, ninu ọ̀ran gbogbo ẹniti iṣe ọmọ iparun.

9. Yà ẹnu rẹ, fi ododo ṣe idajọ, ki o si gbèja talaka ati alaini.

10. Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn.

11. Aiya ọkọ rẹ̀ gbẹkẹle e laibẹ̀ru, bẹ̃ni on kì yio ṣe alaini ère iṣẹ.

12. Rere li obinrin na yio ma ṣe fun u, kì iṣe buburu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo.

13. Obinrin na yio ma ṣafẹri kubusu ati ọ̀gbọ, o si fi ọwọ rẹ̀ ṣiṣẹ tinutinu.

14. O dabi ọkọ̀ oniṣowo: o si mu onjẹ rẹ̀ lati ọ̀na jijin rére wá.

15. On a si dide nigbati ilẹ kò ti imọ́, a si fi onjẹ fun enia ile rẹ̀, ati iṣẹ õjọ fun awọn ọmọbinrin rẹ̀.

16. O kiyesi oko, o si mu u: ère ọwọ rẹ̀ li o fi gbin ọgbà-ajara.

17. O fi agbara gbá ẹ̀gbẹ rẹ̀ li ọjá, o si mu apa rẹ̀ mejeji le.

18. O kiyesi i pe ọjà on dara: fitila rẹ̀ kò kú li oru.

19. O fi ọwọ rẹ̀ le kẹkẹ́-owú, ọwọ rẹ̀ si di ìranwu mu.

20. O nà ọwọ rẹ̀ si talaka; nitõtọ, ọwọ rẹ̀ si kàn alaini.

Ka pipe ipin Owe 31