Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 31:20-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. O nà ọwọ rẹ̀ si talaka; nitõtọ, ọwọ rẹ̀ si kàn alaini.

21. On kò si bẹ̀ru òjo-didì fun awọn ara ile rẹ̀; nitoripe gbogbo awọn ara ile rẹ̀ li a wọ̀ li aṣọ iṣẹpo meji.

22. On si wun aṣọ titẹ́ fun ara rẹ̀; ẹ̀wu daradara ati elese aluko li aṣọ rẹ̀.

23. A mọ̀ ọkọ rẹ̀ li ẹnu-bode, nigbati o ba joko pẹlu awọn àgba ilẹ na.

24. O da aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si tà a, pẹlupẹlu o fi ọjá amure fun oniṣòwo tà.

25. Agbara ati iyìn li aṣọ rẹ̀; on o si yọ̀ si ọjọ ti mbọ.

26. O fi ọgbọ́n yà ẹnu rẹ̀; ati li ahọn rẹ̀ li ofin iṣeun.

27. O fi oju silẹ wò ìwa awọn ara ile rẹ̀, kò si jẹ onjẹ imẹlẹ.

28. Awọn ọmọ rẹ̀ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bãle rẹ̀ pẹlu, on si fi iyìn fun u.

29. Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin li o hùwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ.

30. Oju daradara li ẹ̀tan, ẹwà si jasi asan: ṣugbọn obinrin ti o bẹ̀ru Oluwa, on ni ki a fi iyìn fun.

31. Fi fun u ninu eso-iṣẹ ọwọ rẹ̀; jẹ ki iṣẹ ọwọ ara rẹ̀ ki o si yìn i li ẹnu-bodè.

Ka pipe ipin Owe 31