Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 29:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Talaka ati aninilara enia pejọ pọ̀: Oluwa li o ntan imọlẹ si oju awọn mejeji.

14. Ọba ti o fi otitọ ṣe idajọ talaka, itẹ́ rẹ̀ yio fi idi mulẹ lailai.

15. Paṣan ati ibawi funni li ọgbọ́n: ṣugbọn ọmọ ti a ba jọwọ rẹ̀ fun ara rẹ̀, a dojuti iya rẹ̀.

16. Nigbati awọn enia buburu ba npọ̀ si i, irekọja a pọ̀ si i: ṣugbọn awọn olododo yio ri iṣubu wọn.

17. Tọ́ ọmọ rẹ, yio si fun ọ ni isimi; yio si fi inu-didùn si ọ li ọkàn.

18. Nibiti iran-woli kò si, enia a yapa, ṣugbọn ibukún ni fun ẹniti o pa ofin mọ́.

19. A kì ifi ọ̀rọ kilọ fun ọmọ-ọdọ; bi o tilẹ ye e kì yio dahùn.

20. Iwọ ri enia ti o yara li ọ̀rọ rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.

21. Ẹniti o ba fi ikẹ́ tọ́ ọmọ-ọdọ rẹ̀ lati igba-ewe wá, oun ni yio jogún rẹ̀.

22. Ẹni ibinu ru ìja soke, ati ẹni ikannu pọ̀ ni irekọja.

23. Igberaga enia ni yio rẹ̀ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá.

24. Ẹniti o kó ẹgbẹ ole korira ọkàn ara rẹ̀: o ngbọ́ ifiré, kò si fihan.

Ka pipe ipin Owe 29