Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 28:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́, o ṣe ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ṣe ẹlẹgbẹ jẹguduragudu, o dojuti baba rẹ̀.

8. Ẹniti o fi elé ati ère aiṣõtọ sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di pupọ, o kó o jọ fun ẹniti yio ṣãnu fun awọn talaka.

9. Ẹniti o mu eti rẹ̀ kuro lati gbọ́ ofin, ani adura rẹ̀ pãpa yio di irira.

10. Ẹnikẹni ti o mu olododo ṣìna si ọ̀na buburu, ontikararẹ̀ yio bọ si iho, ṣugbọn aduro-ṣinṣin yio jogun ohun rere.

11. Ọlọrọ̀ gbọ́n li oju ara rẹ̀: ṣugbọn talaka ti o moye ridi rẹ̀.

12. Nigbati awọn olododo enia ba nyọ̀, ọṣọ́ nla a wà; ṣugbọn nigbati enia buburu ba dide, enia a sá pamọ́.

13. Ẹniti o bo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọlẹ kì yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ̀ ọ silẹ yio ri ãnu.

14. Ibukún ni fun ẹniti o bẹ̀ru nigbagbogbo: ṣugbọn ẹniti o ba sé aiya rẹ̀ le ni yio ṣubu sinu ibi.

Ka pipe ipin Owe 28