Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 28:16-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ọmọ-alade ti o ṣe alaimoye pupọ ni iṣe ìwa-ika pupọ pẹlu: ṣugbọn eyiti o korira ojukokoro yio mu ọjọ rẹ̀ pẹ.

17. Enia ti o ba hù ìwa-ika si ẹ̀jẹ ẹnikeji, yio sá lọ si ihò: ki ẹnikan ki o máṣe mu u.

18. Ẹnikẹni ti o ba nrin dẽde ni yio là: ṣugbọn ẹniti o nfi ayidayida rìn loju ọ̀na meji, yio ṣubu ninu ọkan ninu wọn.

19. Ẹniti o ba ro ilẹ rẹ̀ yio li ọ̀pọ onjẹ: ṣugbọn ẹniti o ba ntọ̀ enia asan lẹhin yio ni òṣi to.

20. Olõtọ enia yio pọ̀ fun ibukún: ṣugbọn ẹniti o kanju ati là kì yio ṣe alaijiya.

21. Iṣojuṣãju enia kò dara: nitoripe fun òkele onjẹ kan, ọkunrin na yio ṣẹ̀.

22. Ẹniti o kanju ati là, o li oju ilara, kò si rò pe òṣi mbọ̀wá ta on.

23. Ẹniti o ba enia wi yio ri ojurere ni ikẹhin jù ẹniti nfi ahọn pọn ọ lọ.

Ka pipe ipin Owe 28