25. Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn.
26. Ọmọ mi, fi aiya rẹ fun mi, ki o si jẹ ki oju rẹ ki o ni inu-didùn si ọ̀na mi.
27. Nitoripe agbere, iho jijin ni; ati ajeji obinrin, iho hiha ni.
28. On a si ba ni ibuba bi ole, a si sọ awọn olurekọja di pupọ ninu awọn enia.
29. Tali o ni òṣi? tali o ni ibinujẹ? tali o ni ijà? tali o ni asọ̀? tali o ni ọgbẹ lainidi, tali o ni oju pipọn.
30. Awọn ti o duro pẹ nibi ọti-waini; awọn ti nlọ idan ọti-waini àdalu wò.
31. Iwọ máṣe wò ọti-waini pe o pọn, nigbati o ba fi àwọ rẹ̀ han ninu ago, ti a ngbe e mì, ti o ndùn.
32. Nikẹhin on a buniṣán bi ejò, a si bunijẹ bi paramọlẹ.
33. Oju rẹ yio wò awọn ajeji obinrin, aiya rẹ yio si sọ̀rọ ayidayida.
34. Nitõtọ, iwọ o dabi ẹniti o dubulẹ li arin okun, tabi ẹniti o dubulẹ lòke òpó-ọkọ̀.
35. Iwọ o si wipe, nwọn lù mi; kò dùn mi; nwọn lù mi, emi kò si mọ̀: nigbawo li emi o ji? emi o tun ma wá a kiri.