Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 23:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI iwọ ba joko lati ba ijoye jẹun, kiyesi ẹniti o wà niwaju rẹ gidigidi.

2. Ki o si fi ọbẹ le ara rẹ li ọfun, bi iwọ ba iṣe okundùn enia.

3. Máṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀: nitoripe onjẹ ẹ̀tan ni.

4. Máṣe lãla ati lọrọ̀: ṣiwọ kuro ninu imoye ara rẹ.

5. Iwọ o ha fi oju rẹ wò o? kì yio si si mọ, nitoriti ọrọ̀ hu iyẹ-apá fun ara rẹ̀ bi ìdi ti nfò li oju ọrun.

6. Máṣe jẹ onjẹ oloju buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀.

7. Nitoripe bi o ti nṣiro li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ li o ri: mã jẹ, ki o si ma mu li o nwi fun ọ; ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò pẹlu rẹ.

8. Okele ti iwọ jẹ ni iwọ o pọ̀ jade, iwọ a si sọ ọ̀rọ didùn rẹ nù.

9. Máṣe sọ̀rọ li eti aṣiwère: nitoriti yio gàn ọgbọ́n ọ̀rọ rẹ.

10. Máṣe ṣi àla atijọ; má si ṣe bọ sinu oko alaini-baba.

11. Nitoripe Olurapada wọn lagbara; yio gbà ìja wọn ja ti awọn tirẹ.

12. Fi aiya si ẹkọ́, ati eti rẹ si ọ̀rọ ìmọ.

13. Máṣe fà ọwọ ibawi sẹhin kuro lara ọmọde, nitoripe bi iwọ ba fi paṣan nà a, on kì yio kú.

14. Iwọ fi paṣan nà a, iwọ o si gbà ọkàn rẹ̀ la kuro li ọrun-apadi.

Ka pipe ipin Owe 23