Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 22:6-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Tọ́ ọmọde li ọ̀na ti yio tọ̀: nigbati o si dàgba tan, kì yio kuro ninu rẹ̀.

7. Ọlọrọ̀ ṣe olori olupọnju, ajigbese si ṣe iranṣẹ fun onigbese.

8. Ẹniti o ba funrugbin ẹ̀ṣẹ, yio ri asan ka: ọpá ibinu rẹ̀ si ti mura tan.

9. Ẹniti o li oju ãnu li a o bukun fun; nitoriti o fi ninu onjẹ rẹ̀ fun olupọnju.

10. Ṣá ẹlẹgàn tì sode, ìja yio si jade; nitõtọ ìja ati ẹ̀gan yio dẹkun.

11. Ẹniti o fẹ ìwa funfun aiya, ti o fẹ ọ̀rọ pẹlẹ, ọba yio ṣe ọrẹ́ rẹ̀.

12. Oju Oluwa pa ìmọ mọ́, o si yi ọ̀rọ olurekọja po.

13. Ọlẹ wipe, kiniun mbẹ lode, a o pa mi ni igboro.

14. Ẹnu awọn ajeji obinrin, iho jijin ni; ẹniti a mbinu si lati ọdọ Oluwa wá ni yio ṣubu sinu rẹ̀.

15. Li aiya ọmọde ni wère dì si; ṣugbọn paṣan itọ́ni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ̀.

16. Ẹniti o nni talaka lara lati mu ọrọ̀ pọ̀, ti o si nta ọlọrọ̀ lọrẹ, yio di alaini bi o ti wu ki o ṣe.

17. Dẹti rẹ silẹ, ki o gbọ́ ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n, ki o si fi aiya rẹ si ẹkọ́ mi.

18. Nitori ohun didùn ni bi iwọ ba pa wọn mọ́ ni inu rẹ; nigbati a si pese wọn tan li ète rẹ.

19. Ki igbẹkẹle rẹ ki o le wà niti Oluwa, emi fi hàn ọ loni, ani fun ọ.

20. Emi kò ti kọwe ohun daradara si ọ ni igbimọ ati li ẹkọ́,

21. Ki emi ki o le mu ọ mọ̀ idaju ọ̀rọ otitọ; ki iwọ ki o le ma fi idahùn otitọ fun awọn ti o rán ọ?

22. Máṣe ja talaka li ole, nitori ti iṣe talaka: bẹ̃ni ki o má si ṣe ni olupọnju lara ni ibode:

23. Nitori Oluwa yio gbija wọn, yio si gbà ọkàn awọn ti ngbà lọwọ wọn.

Ka pipe ipin Owe 22