Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 22:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ki emi ki o le mu ọ mọ̀ idaju ọ̀rọ otitọ; ki iwọ ki o le ma fi idahùn otitọ fun awọn ti o rán ọ?

22. Máṣe ja talaka li ole, nitori ti iṣe talaka: bẹ̃ni ki o má si ṣe ni olupọnju lara ni ibode:

23. Nitori Oluwa yio gbija wọn, yio si gbà ọkàn awọn ti ngbà lọwọ wọn.

24. Máṣe ba onibinu enia ṣe ọrẹ́; má si ṣe ba ọkunrin oninu-fùfu rìn.

25. Ki iwọ ki o má ba kọ́ ìwa rẹ̀, iwọ a si gbà ikẹkùn fun ara rẹ.

26. Máṣe wà ninu awọn ti nṣe igbọwọ, tabi ninu awọn ti o duro fun gbèse.

27. Bi iwọ kò ba ni nkan ti iwọ o fi san, nitori kini yio ṣe gbà ẹní rẹ kuro labẹ rẹ?

28. Máṣe yẹ̀ àla ilẹ igbàni, ti awọn baba rẹ ti pa.

29. Iwọ ri enia ti o nfi aiṣemẹlẹ ṣe iṣẹ rẹ̀? on o duro niwaju awọn ọba; on kì yio duro niwaju awọn enia lasan.

Ka pipe ipin Owe 22