11. Ẹniti o fẹ ìwa funfun aiya, ti o fẹ ọ̀rọ pẹlẹ, ọba yio ṣe ọrẹ́ rẹ̀.
12. Oju Oluwa pa ìmọ mọ́, o si yi ọ̀rọ olurekọja po.
13. Ọlẹ wipe, kiniun mbẹ lode, a o pa mi ni igboro.
14. Ẹnu awọn ajeji obinrin, iho jijin ni; ẹniti a mbinu si lati ọdọ Oluwa wá ni yio ṣubu sinu rẹ̀.
15. Li aiya ọmọde ni wère dì si; ṣugbọn paṣan itọ́ni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ̀.
16. Ẹniti o nni talaka lara lati mu ọrọ̀ pọ̀, ti o si nta ọlọrọ̀ lọrẹ, yio di alaini bi o ti wu ki o ṣe.
17. Dẹti rẹ silẹ, ki o gbọ́ ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n, ki o si fi aiya rẹ si ẹkọ́ mi.
18. Nitori ohun didùn ni bi iwọ ba pa wọn mọ́ ni inu rẹ; nigbati a si pese wọn tan li ète rẹ.
19. Ki igbẹkẹle rẹ ki o le wà niti Oluwa, emi fi hàn ọ loni, ani fun ọ.
20. Emi kò ti kọwe ohun daradara si ọ ni igbimọ ati li ẹkọ́,
21. Ki emi ki o le mu ọ mọ̀ idaju ọ̀rọ otitọ; ki iwọ ki o le ma fi idahùn otitọ fun awọn ti o rán ọ?
22. Máṣe ja talaka li ole, nitori ti iṣe talaka: bẹ̃ni ki o má si ṣe ni olupọnju lara ni ibode:
23. Nitori Oluwa yio gbija wọn, yio si gbà ọkàn awọn ti ngbà lọwọ wọn.
24. Máṣe ba onibinu enia ṣe ọrẹ́; má si ṣe ba ọkunrin oninu-fùfu rìn.
25. Ki iwọ ki o má ba kọ́ ìwa rẹ̀, iwọ a si gbà ikẹkùn fun ara rẹ.