Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 21:25-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Ifẹ ọlẹ pa a; nitoriti, ọwọ rẹ̀ kọ̀ iṣẹ ṣiṣe.

26. O nfi ilara ṣojukokoro ni gbogbo ọjọ: ṣugbọn olododo a ma fi funni kì si idawọduro.

27. Ẹbọ enia buburu, irira ni: melomelo ni nigbati o mu u wá ti on ti ìwakiwa rẹ̀?

28. Ẹlẹri eke yio ṣegbe: ṣugbọn ẹniti o gbọ́, yio ma sọ̀rọ li aiyannu.

29. Enia buburu gbè oju rẹ̀ le: ṣugbọn ẹni iduro-ṣinṣin li o nmu ọ̀na rẹ̀ tọ̀.

30. Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa.

31. A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ Oluwa ni.

Ka pipe ipin Owe 21