Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 21:2-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Gbogbo ọ̀na enia li o dara li oju ara rẹ̀: ṣugbọn Oluwa li o nṣe amọ̀na ọkàn.

3. Lati ṣe ododo ati idajọ, o ṣe itẹwọgba fun Oluwa jù ẹbọ lọ.

4. Gangan oju, ati igberaga aiya, ati itulẹ̀ enia buburu, ẹ̀ṣẹ ni.

5. Ìronu alãpọn si kiki ọ̀pọ ni; ṣugbọn ti olukuluku ẹniti o yara, si kiki aini ni.

6. Ini iṣura nipa ahọn eke, o jẹ ẽmi ti a ntì sihin tì sọhun lọwọ awọn ti nwá ikú kiri.

7. Iwa-agbara awọn enia buburu ni yio pa wọn run: nitori ti nwọn kọ̀ lati ṣe idajọ.

8. Ẹnikẹni ti o nrìn ọ̀na ayidayida, enia buburu ni; ṣugbọn oninu funfun ni iṣẹ rẹ̀ tọ́.

9. O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.

10. Ọkàn enia buburu nwá ibi kiri: aladugbo rẹ̀ kò ri ojurere li oju rẹ̀.

11. Nigbati a ba jẹ ẹlẹgàn ni ìya, a sọ òpe di ọlọgbọ́n: nigbati a ba si nkọ́ ọlọgbọ́n, on o ma ni ìmọ.

12. Olododo kiyesi ile enia buburu: pe ẹnikan wà ti yio bì enia buburu ṣubu sinu iparun.

Ka pipe ipin Owe 21