2. Ibẹ̀ru ọba dabi igbe kiniun: ẹnikẹni ti o ba mu u binu, o ṣẹ̀ si ọkàn ara rẹ̀.
3. Ọlá ni fun enia lati ṣiwọ kuro ninu ìja: ṣugbọn olukuluku aṣiwère ni ima ja ìja nla.
4. Ọlẹ kò jẹ tu ilẹ nitori otutu; nitorina ni yio fi ma ṣagbe nigba ikore, kì yio si ni nkan.
5. Ìmọ ninu ọkàn enia dabi omi jijin; ṣugbọn amoye enia ni ifà a jade.
6. Ọ̀pọlọpọ enia ni ima fọnrere, olukuluku ọrẹ ara rẹ̀: ṣugbọn olõtọ enia tani yio ri i.
7. Olõtọ enia nrìn ninu iwa-titọ rẹ̀: ibukún si ni fun awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀!
8. Ọba ti o joko lori itẹ́ idajọ, o fi oju rẹ̀ fọ́n ìwa-ibi gbogbo ka.
9. Tali o le wipe, Mo ti mu aiya mi mọ́, emi ti mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi?