Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 20:16-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Gba aṣọ rẹ̀, nitori ti o ṣe onigbọwọ fun alejo, si gba ohun ẹrí lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin.

17. Onjẹ ẹ̀tan dùn mọ enia; ṣugbọn nikẹhin, ẹnu rẹ̀ li a o fi tarã kún.

18. Igbimọ li a fi ifi idi ete gbogbo kalẹ: ati pẹlu èro rere ni ki o ṣigun.

19. Ẹniti o ba nkiri bi olofofo a ma fi ọ̀ran ìkọkọ hàn: má si ṣe ba ẹniti nṣi ète rẹ̀ ṣire.

20. Ẹnikẹni ti o ba bú baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o pa ninu òkunkun biribiri.

21. Ogún ti a yara jẹ latetekọṣe, li a kì yio bukún li opin rẹ̀.

22. Iwọ máṣe wipe, Emi o gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de Oluwa, on o si gbà ọ.

23. Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, irira ni loju Oluwa; ìwọn irẹjẹ kò si dara.

24. Irin ti enia nrìn, lati ọdọ Oluwa ni; tani ninu awọn enia ti o le mọ̀ ọ̀na rẹ̀?

25. Idẹkùn ni fun enia lati yara ṣe ileri mimọ́, ati lẹhin ẹjẹ́, ki o ma ronu.

26. Ọlọgbọ́n ọba a tú enia buburu ka, a si mu ayika-kẹkẹ́ rẹ̀ kọja lori wọn.

27. Ẹmi enia ni fitila Oluwa, a ma ṣe awari iyara inu.

28. Anu ati otitọ pa ọba mọ́: ãnu li a si fi ndi itẹ́ rẹ̀ mu.

29. Ogo awọn ọdọmọkunrin li agbara wọn: ẹwà awọn arugbo li ewú.

30. Apá ọgbẹ ni iwẹ̀ ibi nù kuro: bẹ̃ si ni ìna ti o wọ̀ odò ikùn lọ.

Ka pipe ipin Owe 20