Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 20:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Kò ni lãri, kò ni lãri li oníbárà iwi; ṣugbọn nigbati o ba bọ si ọ̀na rẹ̀, nigbana ni iṣogo.

15. Wura wà ati iyùn ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn ète ìmọ, èlo iyebiye ni.

16. Gba aṣọ rẹ̀, nitori ti o ṣe onigbọwọ fun alejo, si gba ohun ẹrí lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin.

17. Onjẹ ẹ̀tan dùn mọ enia; ṣugbọn nikẹhin, ẹnu rẹ̀ li a o fi tarã kún.

18. Igbimọ li a fi ifi idi ete gbogbo kalẹ: ati pẹlu èro rere ni ki o ṣigun.

19. Ẹniti o ba nkiri bi olofofo a ma fi ọ̀ran ìkọkọ hàn: má si ṣe ba ẹniti nṣi ète rẹ̀ ṣire.

20. Ẹnikẹni ti o ba bú baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o pa ninu òkunkun biribiri.

21. Ogún ti a yara jẹ latetekọṣe, li a kì yio bukún li opin rẹ̀.

22. Iwọ máṣe wipe, Emi o gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de Oluwa, on o si gbà ọ.

Ka pipe ipin Owe 20