10. Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, bakanna ni mejeji ṣe irira loju Oluwa.
11. Iṣe ọmọde pãpa li a fi imọ̀ ọ, bi ìwa rẹ̀ ṣe rere ati titọ.
12. Eti igbọ́ ati oju irí, Oluwa li o ti dá awọn mejeji.
13. Máṣe fẹ orun sisùn, ki iwọ ki o má ba di talaka; ṣi oju rẹ, a o si fi onjẹ tẹ ọ lọrùn.
14. Kò ni lãri, kò ni lãri li oníbárà iwi; ṣugbọn nigbati o ba bọ si ọ̀na rẹ̀, nigbana ni iṣogo.
15. Wura wà ati iyùn ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn ète ìmọ, èlo iyebiye ni.
16. Gba aṣọ rẹ̀, nitori ti o ṣe onigbọwọ fun alejo, si gba ohun ẹrí lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin.
17. Onjẹ ẹ̀tan dùn mọ enia; ṣugbọn nikẹhin, ẹnu rẹ̀ li a o fi tarã kún.
18. Igbimọ li a fi ifi idi ete gbogbo kalẹ: ati pẹlu èro rere ni ki o ṣigun.
19. Ẹniti o ba nkiri bi olofofo a ma fi ọ̀ran ìkọkọ hàn: má si ṣe ba ẹniti nṣi ète rẹ̀ ṣire.
20. Ẹnikẹni ti o ba bú baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o pa ninu òkunkun biribiri.
21. Ogún ti a yara jẹ latetekọṣe, li a kì yio bukún li opin rẹ̀.