Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 2:9-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nigbana ni iwọ o mọ̀ ododo, ati idajọ, ati aiṣegbe; ani, gbogbo ipa-ọ̀na rere.

10. Nigbati ọgbọ́n bá wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn mọ ọkàn rẹ;

11. Imoye yio pa ọ mọ́, oye yio si ma ṣọ́ ọ:

12. Lati gbà ọ li ọwọ ẹni-ibi, li ọwọ ọkunrin ti nsọrọ ayidayida;

13. Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun;

14. Ẹniti o yọ̀ ni buburu iṣe, ti o ṣe inu-didùn si ayidàyidà awọn enia buburu;

15. Ọ̀na ẹniti o wọ́, nwọn si ṣe arekereke ni ipa-ọ̀na wọn:

16. Lati gbà ọ li ọwọ ajeji obinrin, ani li ọwọ ajeji obinrin ti nfi ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ pọnni;

17. Ẹniti o kọ̀ ọrẹ́ igbà-ewe rẹ̀ silẹ, ti o si gbagbe majẹmu Ọlọrun rẹ̀.

18. Nitoripe ile rẹ̀ tẹ̀ sinu ikú, ati ipa-ọ̀na rẹ̀ sọdọ awọn okú.

19. Kò si ẹniti o tọ̀ ọ lọ ti o si tun pada sẹhin, bẹ̃ni nwọn kì idé ipa-ọ̀na ìye.

20. Ki iwọ ki o le ma rin li ọ̀na enia rere, ki iwọ ki o si pa ọ̀na awọn olododo mọ́.

21. Nitoripe ẹni-iduroṣinṣin ni yio joko ni ilẹ na, awọn ti o pé yio si ma wà ninu rẹ̀.

22. Ṣugbọn awọn enia buburu li a o ke kuro ni ilẹ aiye, ati awọn olurekọja li a o si fàtu kuro ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Owe 2