5. Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ati ẹniti o si nṣeke kì yio mu u jẹ.
6. Ọpọlọpọ ni yio ma bẹ̀bẹ ojurere ọmọ-alade: olukuluku enia ni si iṣe ọrẹ́ ẹniti ntani li ọrẹ.
7. Gbogbo awọn arakunrin talaka ni ikorira rẹ̀: melomelo ni awọn ọrẹ́ rẹ̀ yio ha jina si i? o ntẹle ọ̀rọ wọn, ṣugbọn nwọn kò si.
8. Ẹniti o gbọ́n, o fẹ ọkàn ara rẹ̀: ẹniti o pa oye mọ́ yio ri rere.
9. Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ẹniti o si nṣeke yio ṣegbe.
10. Ohun rere kò yẹ fun aṣiwère; tabi melomelo fun iranṣẹ lati ṣe olori awọn ijoye.
11. Imoye enia mu u lọra ati binu; ogo rẹ̀ si ni lati ré ẹ̀ṣẹ kọja.
12. Ibinu ọba dabi igbe kiniun; ṣugbọn ọjurere rẹ̀ dabi ìri lara koriko.
13. Aṣiwère ọmọ ni ibanujẹ baba rẹ̀: ìja aya dabi ọ̀ṣọrọ òjo.
14. Ile ati ọrọ̀ li ogún awọn baba: ṣugbọn amoye aya, lati ọdọ Oluwa wá ni.
15. Imẹlẹ mu ni sun orun fọnfọn; ọkàn ọlẹ li ebi yio si pa.
16. Ẹniti o pa ofin mọ́, o pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ba kẹgàn ọ̀na rẹ̀ yio kú.
17. Ẹniti o ṣãnu fun talaka Oluwa li o win; ati iṣeun rẹ̀, yio san a pada fun u.
18. Nà ọmọ rẹ nigbati ireti wà, má si ṣe gbe ọkàn rẹ le ati pa a.
19. Onibinu nla ni yio jiya; nitoripe bi iwọ ba gbà a, sibẹ iwọ o tun ṣe e.
20. Fetisi ìmọ ki o si gbà ẹkọ́, ki iwọ ki o le gbọ́n ni igbẹhin rẹ.
21. Ete pupọ li o wà li aiya enia; ṣugbọn ìgbimọ Oluwa, eyini ni yio duro.
22. Ẹwà enia ni iṣeun rẹ̀: talaka enia si san jù eleke lọ.