Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 19:19-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Onibinu nla ni yio jiya; nitoripe bi iwọ ba gbà a, sibẹ iwọ o tun ṣe e.

20. Fetisi ìmọ ki o si gbà ẹkọ́, ki iwọ ki o le gbọ́n ni igbẹhin rẹ.

21. Ete pupọ li o wà li aiya enia; ṣugbọn ìgbimọ Oluwa, eyini ni yio duro.

22. Ẹwà enia ni iṣeun rẹ̀: talaka enia si san jù eleke lọ.

23. Ibẹ̀ru Oluwa tẹ̀ si ìye: ẹniti o ni i yio joko ni itẹlọrun; a kì yio fi ibi bẹ̀ ẹ wọ́.

24. Imẹlẹ enia kì ọwọ rẹ̀ sinu iṣasun, kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu ara rẹ̀.

25. Lu ẹlẹgàn, òpe yio si kiyesi ara: si ba ẹniti o moye wi, oye ìmọ yio si ye e.

26. Ẹniti o ba nṣìka si baba rẹ̀, ti o si le iya rẹ̀ jade, on li ọmọ ti nṣe itiju, ti o si mu ẹ̀gan wá.

Ka pipe ipin Owe 19