Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 18:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ.

18. Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.

19. Arakunrin ti a ṣẹ̀ si, o ṣoro jù ilu olodi lọ: ìja wọn si dabi ọpá idabu ãfin.

20. Ọ̀rọ ẹnu enia ni yio mu inu rẹ̀ tutu: ibisi ẹnu rẹ̀ li a o si fi tù u ninu.

21. Ikú ati ìye mbẹ ni ipa ahọn: awọn ẹniti o ba si nlò o yio jẹ ère rẹ̀.

22. Ẹnikẹni ti o ri aya fẹ, o ri ohun rere, o si ri ojurere lọdọ Oluwa.

23. Talaka a ma bẹ̀ ẹ̀bẹ; ṣugbọn ọlọrọ̀ a ma fi ikanra dahùn.

Ka pipe ipin Owe 18