Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 18:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNITI o yà ara rẹ̀ sọtọ̀ yio lepa ifẹ ara rẹ̀, yio si kọju ìja nla si ohunkohun ti iṣe ti oye.

2. Aṣiwère kò ni inu-didùn si imoye, ṣugbọn ki o le fi aiya ara rẹ̀ hàn.

3. Nigbati enia-buburu ba de, nigbana ni ẹ̀gan de, ati pẹlu ẹ̀gan ni itiju.

4. Ọ̀rọ ẹnu enia dabi omi jijìn, orisun ọgbọ́n bi odò ṣiṣàn.

5. Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ.

6. Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá.

7. Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀.

8. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.

9. Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni.

10. Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.

11. Ọrọ̀ ọlọrọ̀ ni ilu-agbara rẹ̀, o si dabi odi giga li oju ara rẹ̀.

12. Ṣaju iparun, aiya enia a ṣe agidi, ṣaju ọlá si ni irẹlẹ.

Ka pipe ipin Owe 18