Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 15:24-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ọ̀na ìye lọ soke fun ọlọgbọ́n, ki o le kuro ni ipo-okú nisalẹ.

25. Oluwa yio run ile agberaga; ṣugbọn yio fi ìpãlà opó kalẹ.

26. Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀.

27. Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹ̀bun yio yè.

28. Aiya olododo ṣe àṣaro lati dahùn; ṣugbọn ẹnu enia buburu ngufẹ ohun ibi jade.

29. Oluwa jina si awọn enia-buburu; ṣugbọn o gbọ́ adura awọn olododo.

30. Imọlẹ oju mu inu dùn; ihin rere si mu egungun sanra.

31. Ẹniti o ba gbọ́ ibawi ìye, a joko lãrin awọn ọlọgbọ́n.

32. Ẹniti o kọ̀ ẹkọ́, o gàn ọkàn ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba gbọ́ ibawi, o ni imoye.

33. Ibẹ̀ru Oluwa li ẹkọ́ ọgbọ́n; ati ṣãju ọlá ni irẹlẹ.

Ka pipe ipin Owe 15