16. Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀.
17. Onjẹ ewebẹ̀ nibiti ifẹ wà, o san jù abọpa malu lọ ati irira pẹlu rẹ̀.
18. Abinu enia rú asọ̀ soke; ṣugbọn ẹniti o lọra ati binu, o tù ìja ninu.
19. Ọna ọlẹ dabi igbo ẹgún; ṣugbọn ọ̀na olododo já gẽrege ni.
20. Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe ayọ̀ baba; ṣugbọn aṣiwère enia gàn iya rẹ̀.
21. Ayọ̀ ni wère fun ẹniti oye kù fun; ṣugbọn ẹni-oye a ma rìn ni iduroṣinṣin.
22. Laisi ìgbimọ, èro a dasan; ṣugbọn li ọ̀pọlọpọ ìgbimọ, nwọn a fi idi mulẹ.
23. Enia ni ayọ̀ nipa idahùn ẹnu rẹ̀; ati ọ̀rọ kan li akoko rẹ̀, o ti wọ̀ to?
24. Ọ̀na ìye lọ soke fun ọlọgbọ́n, ki o le kuro ni ipo-okú nisalẹ.