4. Nibiti malu kò si, ibujẹ a di ofo: ṣugbọn ibisi pupọ mbẹ nipa agbara malu.
5. Ẹlẹri olõtọ kò jẹ ṣeke: ṣugbọn ẹ̀tan li ẹlẹri eke ima sọ jade.
6. Ẹlẹgan nwá ọgbọ́n, kò si ri i: ṣugbọn ìmọ kò ṣoro fun ẹniti oye ye.
7. Kuro niwaju aṣiwere, ati lọdọ ẹniti kò ni ète ìmọ.
8. Ọgbọ́n amoye ni ati moye ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn iwere awọn aṣiwere li ẹ̀tan.
9. Aṣiwere nfi ẹbi-ẹ̀ṣẹ ṣẹsin: ṣugbọn ojurere wà larin awọn olododo.
10. Aiya mọ̀ ikoro ara rẹ̀; alejo kò si ni iṣe pẹlu ayọ̀ rẹ̀.
11. Ile enia buburu li a o run: ṣugbọn agọ ẹni diduroṣinṣin ni yio ma gbilẹ.