Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 14:16-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ọlọgbọ́n enia bẹ̀ru, o si kuro ninu ibi; ṣugbọn aṣiwère gberaga, o si da ara rẹ̀ loju.

17. Ẹniti o ba tete binu, huwa wère; ẹni eletè buburu li a korira.

18. Awọn òpe jogun iwère; ṣugbọn awọn amoye li a fi ìmọ de li ade.

19. Awọn ẹni-buburu tẹriba niwaju awọn ẹnirere; ati awọn enia buburu li ẹnu-ọ̀na awọn olododo.

20. A tilẹ korira talaka lati ọdọ aladugbo rẹ̀ wá: ṣugbọn ọlọrọ̀ ni ọrẹ́ pupọ.

21. Ẹniti o kẹgàn ẹnikeji rẹ̀, o ṣẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba ṣãnu fun awọn talaka, ibukún ni fun u.

22. Awọn ti ngbìmọ buburu kò ha ṣina bi? ṣugbọn ãnu ati otitọ ni fun awọn ti ngbìmọ ire.

23. Ninu gbogbo lãla li ère pupọ wà: ṣugbọn ọ̀rọ-ẹnu, lasan ni.

24. Adé awọn ọlọgbọ́n li ọrọ̀ wọn: ṣugbọn iwère awọn aṣiwère ni wère.

25. Olõtọ ẹlẹri gbà ọkàn silẹ: ṣugbọn ẹlẹri ẹ̀tan sọ̀rọ eke.

26. Ni ibẹ̀ru Oluwa ni igbẹkẹle ti o lagbara: yio si jẹ ibi àbo fun awọn ọmọ rẹ̀.

27. Ibẹ̀ru Oluwa li orisun ìye, lati kuro ninu ikẹkùn ikú.

28. Ninu ọ̀pọlọpọ enia li ọlá ọba: ṣugbọn ninu enia diẹ ni iparun ijoye.

29. Ẹniti o ba lọra ati binu, o ni ìmọ pupọ; ṣugbọn ẹniti o ba yara binu o gbe wère leke.

30. Ọkàn ti o yè kõro ni ìye ara; ṣugbọn ilara ni ibajẹ egungun.

31. Ẹniti o ba nni talaka lara, o gàn Ẹlẹda rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o ṣãnu fun talaka o bu ọlá fun u.

32. A pa enia buburu run ninu ìwa-buburu rẹ̀; ṣugbọn olododo ni ireti ninu ikú rẹ̀.

33. Ọgbọ́n fi idi kalẹ li aiya ẹniti o moye; ṣugbọn a fi i hàn laiya awọn aṣiwère.

34. Ododo ni igbé orilẹ-ède leke; ṣugbọn ẹ̀ṣẹ li ẹ̀gan orilẹ-ède.

Ka pipe ipin Owe 14