Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 14:12-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara li oju enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú.

13. Ninu ẹrín pẹlu, aiya a ma kãnu; ati li opin, ayọ̀ a di ibinujẹ.

14. Apadasẹhin li aiya ni itẹlọrun lati inu ọ̀na ara rẹ̀: ṣugbọn enia rere lati inu ohun ti iṣe tirẹ̀.

15. Òpe enia gbà ọ̀rọ gbogbo gbọ́: ṣugbọn amoye enia wò ọ̀na ara rẹ̀ rere.

16. Ọlọgbọ́n enia bẹ̀ru, o si kuro ninu ibi; ṣugbọn aṣiwère gberaga, o si da ara rẹ̀ loju.

17. Ẹniti o ba tete binu, huwa wère; ẹni eletè buburu li a korira.

18. Awọn òpe jogun iwère; ṣugbọn awọn amoye li a fi ìmọ de li ade.

19. Awọn ẹni-buburu tẹriba niwaju awọn ẹnirere; ati awọn enia buburu li ẹnu-ọ̀na awọn olododo.

20. A tilẹ korira talaka lati ọdọ aladugbo rẹ̀ wá: ṣugbọn ọlọrọ̀ ni ọrẹ́ pupọ.

21. Ẹniti o kẹgàn ẹnikeji rẹ̀, o ṣẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba ṣãnu fun awọn talaka, ibukún ni fun u.

22. Awọn ti ngbìmọ buburu kò ha ṣina bi? ṣugbọn ãnu ati otitọ ni fun awọn ti ngbìmọ ire.

23. Ninu gbogbo lãla li ère pupọ wà: ṣugbọn ọ̀rọ-ẹnu, lasan ni.

24. Adé awọn ọlọgbọ́n li ọrọ̀ wọn: ṣugbọn iwère awọn aṣiwère ni wère.

25. Olõtọ ẹlẹri gbà ọkàn silẹ: ṣugbọn ẹlẹri ẹ̀tan sọ̀rọ eke.

26. Ni ibẹ̀ru Oluwa ni igbẹkẹle ti o lagbara: yio si jẹ ibi àbo fun awọn ọmọ rẹ̀.

27. Ibẹ̀ru Oluwa li orisun ìye, lati kuro ninu ikẹkùn ikú.

28. Ninu ọ̀pọlọpọ enia li ọlá ọba: ṣugbọn ninu enia diẹ ni iparun ijoye.

29. Ẹniti o ba lọra ati binu, o ni ìmọ pupọ; ṣugbọn ẹniti o ba yara binu o gbe wère leke.

30. Ọkàn ti o yè kõro ni ìye ara; ṣugbọn ilara ni ibajẹ egungun.

31. Ẹniti o ba nni talaka lara, o gàn Ẹlẹda rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o ṣãnu fun talaka o bu ọlá fun u.

Ka pipe ipin Owe 14