Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 13:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌGBỌ́N ọmọ gbà ẹkọ́ baba rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹgàn kò gbọ́ ibawi.

2. Enia yio jẹ rere nipa ère ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ifẹ ọkàn awọn olurekọja ni ìwa-agbara.

3. Ẹniti o pa ẹnu rẹ̀ mọ́, o pa ẹmi rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ṣi ète rẹ̀ pupọ yio ni iparun.

4. Ọkàn ọlẹ nfẹ, kò si ri nkan; ṣugbọn ọkàn awọn alãpọn li a o mu sanra.

5. Olododo korira ẹ̀tan; ṣugbọn enia buburu mu ni hu ìwa irira on itiju.

6. Ododo pa aduro-ṣinṣin li ọ̀na mọ́; ṣugbọn ìwa-buburu ni imuni ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ.

7. Ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe ọlọrọ̀, ṣugbọn kò ni nkan; ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe talaka ṣugbọn o li ọrọ̀ pupọ.

8. Irapada ẹmi enia li ọrọ̀ rẹ̀; ṣugbọn olupọnju kò kiyesi ibawi.

Ka pipe ipin Owe 13