17. Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan.
18. Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni.
19. Ete otitọ li a o mu duro lailai; ṣugbọn ahọn eke, ìgba diẹ ni.
20. Ẹtan wà li aiya awọn ti nrò ibi: ṣugbọn fun awọn ìgbimọ alafia, ayọ̀ ni.
21. Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi.
22. Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀.
23. Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere.
24. Ọwọ alãpọn ni yio ṣe akoso; ṣugbọn ọlẹ ni yio wà labẹ irú-sisìn.
25. Ibinujẹ li aiya enia ni idori rẹ̀ kọ odò; ṣugbọn ọ̀rọ rere ni imu u yọ̀.
26. Olododo tọ́ aladugbo rẹ̀ si ọ̀na; ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu tàn wọn jẹ.
27. Ọlẹ enia kò mu ohun ọdẹ rẹ̀; ṣugbọn lati jẹ alãpọn enia, ọrọ̀ iyebiye ni.
28. Li ọ̀na olododo ni ìye; ikú kò si loju ọ̀na otitọ.