Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 10:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ibukún ni iranti olõtọ: ṣugbọn orukọ enia buburu yio rà.

8. Ọlọgbọ́n inu ni yio gbà ofin: ṣugbọn ete werewere li a o parun.

9. Ẹniti o nrìn dede, o rìn dajudaju: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ayida ọ̀na rẹ̀, on li a o mọ̀.

10. Ẹniti nṣẹ́ oju o mu ibanujẹ wá: ṣugbọn ète werewere li a o parun.

11. Kanga ìye li ẹnu olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu.

12. Irira ni irú ìja soke: ṣugbọn ifẹ bò gbogbo ẹ̀ṣẹ mọlẹ.

13. Li ète ẹniti o moye li a ri ọgbọ́n: ṣugbọn kùmọ ni fun ẹhin ẹniti oye kù fun.

14. Awọn ọlọgbọ́n a ma to ìmọ jọ: ṣugbọn ẹnu awọn aṣiwere sunmọ iparun.

15. Ọrọ̀ ọlọlà ni agbára rẹ̀: aini awọn talaka ni iparun wọn.

16. Iṣẹ olododo tẹ̀ si ìye; èro awọn enia buburu si ẹ̀ṣẹ.

17. Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna.

18. Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni.

Ka pipe ipin Owe 10