Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oni 7:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ORUKỌ rere dara jù ororo ikunra; ati ọjọ ikú jù ọjọ ibi enia lọ.

2. O dara lati lọ si ile ọ̀fọ jù ati lọ si ile àse: nitoripe eyi li opin gbogbo enia; alãye yio si pa a mọ́ li aiya rẹ̀.

3. Ibinujẹ san jù ẹrín: nitoripe nipa ifaro oju a si mu aiya san.

4. Aiya ọlọgbọ́n mbẹ ni ile ọ̀fọ; ṣugbọn aiya aṣiwère ni ile iré.

5. O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère.

6. Nitoripe bi itapàpa ẹgún labẹ ìkoko, bẹ̃li ẹrín aṣiwère: asan li eyi pẹlu.

7. Nitõtọ inilara mu ọlọgbọ́n enia sinwin; ọrẹ a si ba aiya jẹ.

8. Opin nkan san jù ipilẹṣẹ rẹ̀ lọ: ati onisuru ọkàn jù ọlọkàn igberaga.

9. Máṣe yara li ọkàn rẹ lati binu, nitoripe ibinu simi li aiya aṣiwère.

10. Iwọ máṣe wipe, nitori kili ọjọ iṣaju ṣe san jù wọnyi lọ? nitoripe iwọ kò fi ọgbọ́n bere niti eyi.

11. Ọgbọ́n dara gẹgẹ bi iní, ati nipasẹ rẹ̀ ère wà fun awọn ti nri õrùn.

12. Nitoripe ãbò li ọgbọ́n, ani bi owo ti jẹ́ abò: ṣugbọn ère ìmọ ni pe, ọgbọ́n fi ìye fun awọn ti o ni i.

13. Wò iṣẹ Ọlọrun: nitoripe, tali o le mu eyini tọ́ ti on ṣe ni wiwọ?

14. Li ọjọ alafia, mã yọ̀, ṣugbọn li ọjọ ipọnju, ronu pe, bi Ọlọrun ti da ekini bẹ̃li o da ekeji, niti idi eyi pe ki enia ki o máṣe ri nkan ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀.

Ka pipe ipin Oni 7