Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oni 2:12-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Mo si yi ara mi pada lati wò ọgbọ́n, ati isinwin ati iwère: nitoripe kili ọkunrin na ti mbọ lẹhin ọba yio le ṣe? eyi ti a ti ṣe tan nigbani ni yio ṣe.

13. Nigbana ni mo ri pe ọgbọ́n ta wère yọ, to iwọn bi imọlẹ ti ta òkunkun yọ.

14. Oju ọlọgbọ́n mbẹ li ori rẹ̀; ṣugbọn aṣiwère nrìn li òkunkun: emitikalami si mọ̀ pẹlu pe, iṣe kanna li o nṣe gbogbo wọn.

15. Nigbana ni mo wi li aiya mi pe, Bi o ti nṣe si aṣiwère, bẹ̃li o si nṣe si emitikalami; nitori kili emi si ṣe gbọ́n jù? Nigbana ni mo wi li ọkàn mi pe, asan li eyi pẹlu.

16. Nitoripe iranti kò si fun ọlọgbọ́n pẹlu aṣiwère lailai; ki a wò o pe, bi akoko ti o kọja, bẹ̃li ọjọ ti mbọ, a o gbagbe gbogbo rẹ̀. Ọlọgbọ́n ha ṣe nkú bi aṣiwère?

17. Nitorina mo korira ìwa-laiye: nitoripe iṣẹ ti a ṣe labẹ õrun: ibi ni fun mi: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo.

18. Nitõtọ mo korira gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn: nitoriti emi o fi i silẹ fun enia ti mbọ̀ lẹhin mi.

19. Tali o si mọ̀ bi ọlọgbọ́n ni yio ṣe tabi aṣiwère? sibẹ on ni yio ṣe olori iṣẹ mi gbogbo ninu eyi ti mo ṣe lãla, ati ninu eyi ti mo fi ara mi hàn li ọlọgbọ́n labẹ õrùn. Asan li eyi pẹlu.

20. Nitorina mo kirilọ lati mu aiya mi ṣí kuro ninu gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn.

21. Nitoriti enia kan mbẹ, iṣẹ ẹniti o wà li ọgbọ́n ati ni ìmọ, ati ni iṣedẽde; sibẹ ẹniti kò ṣe lãla ninu rẹ̀ ni yio fi i silẹ fun ni ipin rẹ̀. Eyi pẹlu asan ni ati ibi nlanla.

22. Nitoripe kili enia ni ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o fi nṣe lãla labẹ õrùn?

23. Nitoripe ọjọ rẹ̀ gbogbo, ikãnu ni, ati iṣẹ rẹ̀, ibinujẹ, nitõtọ aiya rẹ̀ kò simi li oru. Eyi pẹlu asan ni.

Ka pipe ipin Oni 2