Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oni 2:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI wi ninu mi pe, wá na! emi o fi iré-ayọ̀ dan ọ wò, nitorina mã jẹ afẹ! si kiyesi i, asan li eyi pẹlu!

2. Emi wi fun ẹrin pe, Iwère ni ọ: ati fun iré-ayọ̀ pe kili o nṣe?

3. Mo rò ninu aiya mi lati fi ọti-waini mu ara mi le, ṣugbọn emi nfi ọgbọ́n tọ́ aiya mi: on ati fi ọwọ le iwère, titi emi o fi ri ohun ti o dara fun ọmọ enia, ti nwọn iba mã ṣe labẹ ọrun ni iye ọjọ aiye wọn gbogbo.

4. Mo ṣe iṣẹ nla fun ara mi; mo kọ́ ile pupọ fun ara mi; mo gbin ọgbà-ajara fun ara mi.

5. Mo ṣe ọgbà ati agbala daradara fun ara mi, mo si gbin igi oniruru eso sinu wọn.

6. Mo ṣe adagun pupọ, lati ma bomi lati inu wọn si igbo ti o nmu igi jade wá:

7. Mo ni iranṣẹ-kọnrin ati iranṣẹ-birin, mo si ni ibile; mo si ni ini agbo malu ati agutan nlanla jù gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ṣaju mi.

8. Mo si kó fadaka ati wura jọ ati iṣura ti ọba ati ti igberiko, mo ni awọn olorin ọkunrin ati olorin obinrin, ati didùn inu ọmọ enia, aya ati obinrin pupọ.

9. Bẹ̃ni mo tobi, mo si pọ̀ si i jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju mi ni Jerusalemu: ọgbọ́n mi si mbẹ pẹlu mi.

10. Ohunkohun ti oju mi fẹ, emi kò pa a mọ́ fun wọn; emi kò si dù aiya mi li ohun ayò kan; nitoriti aiya mi yọ̀ ninu iṣẹ mi gbogbo; eyi si ni ipin mi lati inu gbogbo lãla mi.

11. Nigbati mo wò gbogbo iṣẹ ti ọwọ mi ṣe, ati lãla ti mo ṣe lãla lati ṣe: si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo, ko si si ère kan labẹ õrùn.

Ka pipe ipin Oni 2