Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oni 11:8-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ṣugbọn bi enia wà li ọ̀pọlọpọ ọdun, ti o si nyọ̀ ninu gbogbo wọn, sibẹ, jẹ ki o ranti ọjọ òkunkun pe nwọn o pọ̀. Ohun gbogbo ti mbọ̀, asan ni.

9. Mã yọ̀, iwọ ọdọmọde ninu ewe rẹ; ki o si jẹ ki ọkàn rẹ ki o mu ọ laraya li ọjọ ewe rẹ, ki o si ma rìn nipa ọ̀na ọkàn rẹ ati nipa irí oju rẹ; ṣugbọn iwọ mọ̀ eyi pe, nitori nkan wọnyi Ọlọrun yio mu ọ wá si idajọ.

10. Nitorina ṣi ibinujẹ kuro li aiya rẹ, ki o si mu ibi kuro li ara rẹ: nitoripe asan ni igba-ewe ati ọmọde.

Ka pipe ipin Oni 11