5. Buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, bi ìṣina ti o ti ọdọ awọn ijoye wá.
6. A gbe aṣiwère sipò ọlá, awọn ọlọrọ̀ si joko nipò ẹhin.
7. Mo ri awọn ọmọ-ọdọ lori ẹṣin, ati awọn ọmọ-alade nrìn bi ọmọ-ọdọ ni ilẹ.
8. Ẹniti o wà iho ni yio bọ́ sinu rẹ̀; ati ẹniti o si njá ọgbà tútù, ejo yio si bù u ṣán.
9. Ẹnikan ti o nyi okuta ni yio si ti ipa rẹ̀ ni ipalara; ati ẹniti o si nla igi ni yio si wu li ewu.
10. Bi irin ba kújú, ti on kò si pọn oju rẹ̀, njẹ ki on ki o fi agbara si i; ṣugbọn ère ọgbọ́n ni lati fi ọ̀na hàn.
11. Nitõtọ bi ejo ba bu ni ṣán lainitùju; njẹ ère kì yio si fun onitùju.
12. Ọ̀rọ ẹnu ọlọgbọ̀n li ore-ọfẹ; ṣugbọn ète aṣiwère ni yio gbe ara rẹ̀ mì.
13. Ipilẹṣẹ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni wère: ati opin ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni isinwin iparun.
14. Aṣiwère pẹlu kún fun ọ̀rọ pupọ: enia kò le sọ ohun ti yio ṣẹ; ati ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀, tali o le wi fun u?
15. Lãla aṣiwère da olukuluku wọn li agara, nitoriti kò mọ̀ bi a ti lọ si ilu.
16. Egbé ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba ṣe ọmọde, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun ni kutukutu.
17. Ibukún ni fun ọ, iwọ ilẹ, nigbati ọba rẹ ba jẹ ọmọ ọlọlá, ti awọn ọmọ-alade rẹ njẹun li akoko ti o yẹ, fun ilera ti kì si iṣe fun ọti amupara!